15879. E Yo Ninu Oluwa

1 E yo ninu Oluwa, E yo
Eyin t’okan re se dede
Eyin t’o ti yan Oluwa
L’ibanuje ati aro lo.

Egbe:
E yo, e yo
E yo nin’Oluwa e yo
E yo, E yo
E yo nin’Oluwa e yo.

2 E yo, to r’oun l’Oluwa
L’aye ati l’orun pelu
Oro re bor’ohun gbogbo
O l’agbara l’ati gbala. [Egbe]

3 Gba t’a ba n ja ija rere
Ti ota fere bori yin
Ogun Olorun t’a ko ri
Poju awon ota yin lo. [Egbe]

4 B’okunkun ti le yi o ka
Pelu isudede gbogbo
Mase je k’Okan re damu
Sa gbekel’Oluwa d’opin. [Egbe]

5 E yo ninu Oluwa, e yo
E k’orin iyin re kikan
Fi duru ati ohun ko
Halleluyah l’ohun goro. [Egbe]

Text Information
First Line: E yo ninu Oluwa, E yo
Title: E Yo Ninu Oluwa
English Title: Be glad in the Lord, and rejoice
Author: Mary E. Servoss
Translator: Anonymous
Refrain First Line: E yo, e yo
Language: Yoruba
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: [E yo ninu Oluwa, E yo]
Composer: James McGranahan
Key: B♭ Major
Copyright: Public Domain



Media
MIDI file: MIDI
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us