15893. Mo Ti Seleri Jesu

1 Mo ti seleri Jesu,
Lati sin O dopin;
Ma wa lodo mi titi,
Baba mi Ore mi.
Emi k’yo beru ogun,
B’Iwo ba sun mo mi,
Emi ki y’o si sina,
B’O ba fona han mi.

2 Je ki n mo p’O sunmo mi,
’Tori’baje aiye;
Aiye fe gba okan mi,
Aiye fe tan mi je,
Ota yi mi ka,kiri,
Lode ati ninu;
Sugbon Jesu, sunmo mi,
Dabobo okan mi.

3 Je ki emi k’ o ma gbo,
Ohun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo.
So k’ o f’ okan mi bale,
Teri okan mi ba;
So k’ emi le gbo Tire,
’Wo Olutoju mi.

4 ’Wo ti se ’leri Jesu,
F’awon t’ o tele O,
Pe ibikibi t’O wa,
Lawon yio si wa;
Mo ti se ’leri Jesu,
Lati sin O dopin.
Je ki n ma to O lehin,
Baba mi, Ore mi.

5 Je ki n ma ri ’pase Re,
Ki n le ma tele O;
Agbara Re nikan ni,
Ti m’ ba le tele O:
To mi, pe mi, si fa mi
Di mi mu de opin,
Si gba mi si odo Re,
Baba mi, Ore mi.

Text Information
First Line: Mo ti seleri Jesu
Title: Mo Ti Seleri Jesu
English Title: O Jesus, I have promised
Author: John E. Bode
Translator: Anonymous
Meter: 76.76 D
Language: Yoruba
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: DAY OF REST
Composer: James William Elliott
Meter: 76.76 D
Key: F Major or modal
Copyright: Public Domain



Media
Adobe Acrobat image: PDF
MIDI file: MIDI
Noteworthy Composer score: Noteworthy Composer Score
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us