15904. Oluwa, Emi a Ti Gbohun Re

1 Oluwa, emi sa ti gbohun Re,
O nso ife Re si mi;
Sugbon mo fe dide lapa igbagbo
Kin le tubo sun mo O.

Egbe:
Fa mi mora, mora Oluwa,
Sibi agbelebu t’Oku.
Fa mi mora, mora, Oluwa
S’ ibi eje Re to niye.

2 Ya mi si mimo fun ise tire,
Nipa ore-ofe Re;
Je ki nfi okan igbagbo woke,
K’ife mi le se Tire. [Egbe]

3 A! ayo mimo ti wakati kan
Ti mo lo nib’ite Re,
’Gba mo ngbadura, si Olorun mi,
Ti a soro bi ore! [Egbe]

4 Ijinle ife mbe ti nko le mo
Titi ngo koja odo;
Ayo giga ti emi ko le so
Titi ngo fi de ’sinmi. [Egbe]

Text Information
First Line: Oluwa, emi sa ti gbohun Re
Title: Oluwa, Emi a Ti Gbohun Re
English Title: I am Thine, O Lord, I have heard Thy voice
Author: Fanny Crosby
Refrain First Line: Fa mi mora, mora Oluwa
Language: Yoruba
Copyright: Public Domain
Tune Information
Name: [Oluwa, emi sa ti gbohun Re]
Composer: William Howard Doane
Key: A♭ Major
Copyright: Public Domain



Media
MIDI file: MIDI
More media are available on the tune authority page.

Suggestions or corrections? Contact us